Versos O fúndìí en Ofun-Odi

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos O fúndìí en Ofun-Odi

O fúndìí
Ò n só
O sòrò
O ò bèbè
O sì tún ní kí wón ó gbé oníkòjú wá
A díá fún Purópuró alé àná
Èyí tí ó dójà ti ó puró mó omoo rè
Ìyá àgbà purópuró ló dé ojà
Ló sì pon omo è lo
Nígbà ó dé ààrin ojà
Bó ti bèrè kó móo ra ojà
Àfi pùú
Ló bá só
Sísó tó só báyìí
Pàá, ló gbá omo è nídìí
Ó níwo omo yìí
Lò sì wáá só pa gbogboo wa báhun
Omó bá gbó
Òun nìyá òún puró mó tó bayìí?
Omó bá bú sékún
Wón e wolé
Omó sunkún sunkún
Omo ò tún dáké
Wón wáá se see se
Bóo làwon ó ti wáá se?
Wón bá to Òrúnmìlà lo
Gba àwon dákun!
Àwòyeróye Awo Ilé Òrúnmìlà
Ó ní ‘Ìwo ìyá yìí lo se ihun tí omó fí n sunkún’
‘Ó ní kínni kan tóo se fún omo yìí ni kóo yáa rántí’
Ìyá rántí rántí
Ó ní àfi lója náà ni
Tóun gbé só làárin gbogbo èèyàn
Tóun ní omo yìí ló só
Òrúnmìlà ní ‘O ó tùún padà lo ojà òhún’
‘Kó o wáá móo fenu araà re wí’
‘Pé Onísó alé àná tó só’
‘Omo kó o’
‘Èmi ni mo só o’
Omo òun kó o
Òun lòún só o
Ìyá bá padà lo ojà
Ní bá n pé gbogbo ará ojá
Isó alé àná
Òun lòún só o
Kéè se omo òun o
Omó bá dáké ekún
Ó lóo fúndìí
Ò n só
O sòrò
O ò bèbè
O sì tún ní kí wón ó gbé oníkòjú wá
A díá fún Purópuró alé àná
Èyí tí ó dójà tí ó sòó tán
Tí ó puró mó omoo rè
Onísó alé àná o
Ìyá mòmò ló só o
Omoo rè mòmò kó o
Onísó alé àná.

Véase Ofun-Odi.