Versos de Adábàá en Odi-Otura
Versos de Adábàá en Odi-Otura
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jeku
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jẹja
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jeran
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è tétéété
Àwon Adábàá jeku
Wón ń dábàá jeku lo lásán
Àwon Adábàá jeja
Wón ń dábàá jeja lásán
Àwon Adábàá jeran
Wón ń dábàá jeran lásán
Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è ló wò ó pé “àkójo tòun ó se yìí”
“Eran tóun féé pa”
“Kílé òún ó kún”
“Kó pò fún èèyàn”
“Kí gbogbo è ó móo dùn yìín”
Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è ò se méjì mó
Eran ní ń pa
Ní ó kòó gbogbo omo è jo
Àti Obìnrin è
Gbogboo wón ó móo jeun
Wón ó móo mu
Wón ó móo yò
Àwon èèyàn bá wòye
“Àwon Adábàá jeku, adábàá jeja, àti àwon adábàá jeran tí ón ń dáá ń lo yìí”
“Wón è é sèèyàn”
“Àwon Adábàá kúnlée bàbá è tétéété”
“Àwon la mò”
“Ló kó gbogbo ebí è jo yìí
“To peraán lè”
“Tí gbogboo wón ń jeun”
Bó ti kún níhìín yìí
Béè náà ní ó kùún lóhùún
Wón ní ayé gbodò ye é
Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è nìkan layé ye
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo ń yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jeku
N dábàá jeku lásán ni
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jeja
N dábàá jeja lásán ni
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá jeran
N dábàá jeran lásán ni
Ìdin àfàgò kéyin àparò
N tójú bá wá lójúú rí
A dífá fún Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è tétéété
Taa ló seun to sèèyàn?
Adábàá nìkàn kúnlée bàbá è tétéété
N ló seun
N ló sèèyàn.
Véase Odi-Otura.