Versos de Dùndún en Odi-Ogunda

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Dùndún en Odi-Ogunda

Dinndinnkúdá
Dìnndìnnkúdá
A díá fún Dùndún
Tí tí n rìn ní kòkò
Tí tí n rìn ní bàábá
Wón ní kó rúbo kó le deni òkánkán gbangba
Wón ní òpòlopò eyelé lebo
Òpòlopò owó lebo
Awoo pálà lebo
Won è é tíí pé Dùndún télè rí
Dùndún sà á n be ní kòrò
Ngbà ó rúbo tán
Ó bá dojó kan
Wón bá ní wón ó lòó pè é wá láti Ààfìn
Òun náà?
Ìgbà ó dé òhún
Dùndún té gbàjá aré sílè
Gbogbo ihun ti àwon ìlù tó kù ò le se
Dùndún bá se gbogbo è
Wón ní eni tí ó móo lù fún Oba jó láíláí nìyí o
Ni Dùndún bá n jó ní n yò
Ní n yin àwon Dinndinnkúdá àti Dìnndìnnkúdá
Àwon Babaláwo è n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Dinndinnkúdá
Dìnndìnnkúdá
A díá fún Dùndún
Tí tí n rìn ní kòkò
Tí tí n rìn ní bàábá
Wón ní kó rúbo kó le deni òkánkán gbangba
Mo mòmò yin Dinndinnkúdá
Mo yin Dìnndìnnkúdá
Dùndún tí tí n rìn ní kòkò
Dùndún wáá deni òkánkán gbangba
Mo yin Dinndinnkúdá
Mo yin Dìnndìnnkúdá o
Mo wáá deni òkánkán gbangba.

Véase Odi-Ogunda.