Versos de Odíderé en Obara-Odi

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Odíderé en Obara-Odi

Òbàrà ò bòdí
Ìdí ò mó lé
E jé kanhinkanhin ilée yín ó ta yín díe
A díá fún Odíderé
Omo a fosù gbogbo sòwò èjè
Wón ní kó rúbo
Kó fidí è mólé
Kò gbóràn
Wón bá pè e léyìn odi
Pírí ló sídìí
Ló bá korí sí Ilé Ifè
Ó kúó nílé è
Yóó lòó ra isu
Ó dé Ilé Ifè
Kò bá isu mó
Kànhìnkànhìn ló kù
Àwon ti ta isu tán nlé Ifè
‘Kànhìnkànhìn tó kú nlè nùu’
Nílé tó ti kúò
Wón ti kó isu dé ibè
Kó tóó padà dé ilé
Àwon náà ti tà tán
Wón làwon ò wí fún o
Pé kóo fara balè
Ifá lóun wí fún o
Pé o móo bi òun leeré
Kóo tóó le móo yún àjò
Ibi tóun bá ní kóo móo lo
Kó mò pé àkókò è ló tó
Ló bá padàá lé
Ló bá bèrè síí fìdí mólé
Òbàrà ò bòdí
Ìdí ò mó lé
E jé kanhinkanhin ilée yín ó ta yín díe
A díá fún Odíderé
Omo a fosù gbogbo sòwò èjè
Yóó mòmò domo
Òwò èjè kan
Òwò èjè kàn
Táa se lósu yìí
Yóó mòmò domo
Omo ní ó mòmò dà.

Véase Obara-Odi.