Versos de Ológbò jígòlò en Iroso-Oshe
Ir a la navegación
Ir a la búsqueda
Versos de Ológbò jígòlò en Iroso-Oshe
Ajìwáwá jìwowo òpè ni ò seé gbòn rìrì ko
A dífá fún Ológbò jígòlò
Ti ń lo rèé bímo sénu àjé
“Ibi tí òún bímo sí yìí?”
“Nňkan ò mú àwon omo òun báyìí?”
Wón ní kó rúbo
Ológbò jígòlò bá rúbo
Bí ón bá gbé omo è báyìí
Ti ón ń pé àwon ó yè é wò
A pé “òhun ni”
“Òhun ni”
Ni ón ba ń jùúlè
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo ń yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ajìwáwá jìwowo òpè ni ò seé gbòn rìrì ko
A dífá fún Ológbò jígòlò
Ti ń lo rèé bímo sénu àjé
Eléyìí ńkó?
Awo ni
Onítòhún ńkó?
Awo ni
Awo lOlógbò jígòlò tó bímo sénu àjé.
Véase Iroso-Oshe.