Versos de Àkèsán en Odi-Meyi

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Àkèsán en Odi-Meyi

Kóróbótó kóróbótó ni wóón pilè àwon
Bó bá dókè a gbìbú
A móo gbomorí odó
A móo gbomorí olo
A dífá fún Àkèsán
Àkèsán tíí se baálè ojà olówó
Àkèsán lojà àkódá ńlé ayé
Oba ló sì ni í
Obìnrin sí ni Oba òhún
Wón ní kó rúbo
Ó bá rúbo
Ó rú ohun gbogbo nígbà nígbà
Gbogbo ayé bá Àkèsán pé
Tée dòní ní wón ń nájà Àkèsán
Gbogbo ojà tó kù tí wón dá
Àkèsán ní bàbá gbogboo won
Ifá pé ayé ó ye eni ó dá Ifá yìí
Ó tóbi tán ní ń yin Ifá
Ifá ń yin Olódùmarè Oba
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Kóróbótó kóróbótó ni wóón pilè àwon
Bó bá dókè a gbìbú
A móo gbomorí odó
A móo gbomorí olo
A dífá fún Àkèsán baálè Ojà Olówó
Wón ní ó rúbo kó lè baà tóbi
Kó lè baà deni ńlá láyé
Àkèsán gbébo ńbè
Ó rúbo
Rírú ebo
Èèrù àtùkèsù
E wáá bá ni ní jèbútú ire
Jèbútú ire làá bá ni lésè Oba Òrìsà
Àkèsán mòmò dé ò
Báàlè ojà
Báa bá rólórí rere
À á dájà.

Véase Odi-Meyi.