Versos de Èkó en Iroso-Otrupon
Ir a la navegación
Ir a la búsqueda
Versos de Èkó en Iroso-Otrupon
Èkó kó won yún
Èkó kó won bò
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí ń lo Àgbá ègbò Ifè Olúkiribítí
Àgbá ègbò Ifè Olúkiribítí tóun ń lo yìí dáa báyìí?
Wón níwo Òrúnmìlà
“Wón lóó móo lo dáadáa”
“Ó móo bò dáadáa”
Wón ní “Ògún ní kóo lòó bo”
Ó bá bo Ògún
Àwon sì ń gbógun lÁgbàá ègbò ifè Olúkiribítí
Wón níwo Òrúnmìlà ó la ogun òhún kojá
Wón ní kò níí sí kinní kan tí ó mu
Wón ní ó móo dárin
N ni àwon Ológun ń se tée dòní
Èkó kó won yún
Èkó kó won bò
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí ń lo Àgbá ègbò Ifè Olúkiribítí
Wón ní kó rúbo kó lè baà ségun
Òrúnmìlà gbébo ńbè ó rúbo
Èkó kó won yún
Èkó kó won bò
Awo rere lÈkóó se
Héè
Awo rere lÈkóó se
Héè.
Véase Iroso-Otrupon.