Versos de Òbàrà Ìretè en Obara-Irete
Versos de Òbàrà Ìretè en Obara-Irete
Yangí aborí kugúkugú
A díá fún Olóbàrà
Èyí tí n lo rèé bá won dá oko èbá ònà
Wón ní ó rúbo kó lè baà ráya rere ní
Òun leè láya rere báyìí?
Wón ní kó mó sahun
Kò se méjì mó
Esè ònà ní n fi oúnje sí
Fún gbogbo àwon èèyàn tí bá n kojáá lo
Sé nígbà ìwásè
Eni tí n lo ìrìn àjò
Tí ebí sì n pa
Yóó bàá nnkan tí ó je
Àti omi tí ó mu lésè ònà
Wón ní kí Olóbàrà ó móo se béè
Wón níre n bò fún un
Àwon tí ón wáá móo kojá nígbà gbogbo
Wón bá ní ‘Ibi táwòón tíí móo kojá yìí’
‘E jé àwon ó kúkú fi ibè se ibùjokòó’
Wón bá te ìlú dó
Wón bá fi Olóbàrà joba
Wón fi se babaa won
Ení ó bá sì joba
Ó di dandan kó ráya fé
Wón bá tun fún Olóbàrà níyàwó
N ní wá n jó n ní wá n yò
N yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Yangí aborí kugúkugú
A díá fún Olóbàrà
Èyí tí n lo rèé bá won dá oko èbá ònà
Wón ní ó rúbo
Kó rúbo kó lè baà ráya rere ní
Ó gbébo nbè
Ó rúbo
Njé ayá wolé tò wá gerere
Olóbàrà
Ayá wáá wolé tò wá gerere
Olóbàrà.
Véase Obara-Irete.