Versos de Sàsóré y Eléwìí en Iwori-Irete
Versos de Sàsóré y Eléwìí en Iwori-Irete
Orí wo ibi rere gbé mi dé
Èsè wo ibi rere sìn mí rè
Ibi Oríi mi n gbé mií rè
N ò mo be
A díá fún Sàsóré
Èyí ti n lo rèé borí Eléwìí
Bí Eléwìí ó bàá sodún
A móo rawó
Jóun ó sèèmíìn
Mó jóun ó ráìda
Jóun ó rójú
Má jèé nnkan ó somo òun
Má jèé ó sobìnrin òun
Jémìí òun ó gùn
Jé kí òna ó là fún òun
Má jèé kí ònà ó dí mó òun
Ònà è é dí mó Aládàá
Jésin Oba ó jeko pé
Jé kí Àgàn ó tówó ààlà bo Osùn
Káboyún ó bí tibi tire
Eléwìí ó bàá ké sí Sàsóré
Pé kó wáá fàse sí I
Sàsóré náà ó bòó bè
Yóó máa wúre fún Eléwìí
Jé ó dáa fún Eléwìí
Jé ó rí ná
Jé ó rí lò
Sùgbón jé ó dáa fún òun náà
Gbé òun náà dé ibí ó dáa
Ó ti n wí béè tipé
Ìgbà ó yá. Eléwìí ní
“Èsín èyí yìí”
Níbo loríì ré n gbé o rè?
Kí Oríì re ó gbé o dé ibo?
Yóó sì gbé o dé ibìkan
Eléwìí bá lòó kan pósí òhún
Wón bá kàn án pa
Ó ní kí wón ó lo jù ú sínú odò
Omí bá gbé pósí lo
Eléwìí ní “ibi oríì re ó gbèé o dé òún ó rí I”
“Òún ní o wúre fún òun”
“Ìwó n wúre fún araà re”
“Oní kínni o”?
Ní Ìbínní, àlejò ni ón sì fíí joyè
Òpá oyè sì sé lóhùún
Àwon wáá rù ú wón sò ó
Ifá yìí ni wón dá
Ifá ní kí wón ó móo lo odò
Pé wón ó rìí nnkan àmì lójú omi
Ó ní kí wón ó mú ohun ti wón bá rí
Olúwa è ní ó joba
Ìgbà àwón dé etí omi léyìn ojó meje
Wón bá rí pósí lójú omi
Omí n gbé pósí bò
Ní n tàkìtì
Àwon Oníkèngbè bá bóójú omi
Wón n wedò lòó bá pósí
Wón bá gbé e jáde
Wón bá gé pósi níbùú
Bí ón ti si pósi
Èèyàn ni ón bá nnú è
Wón ba gbé e
Ijó ni ón n jó lo láti ibè
Ní ón n se
“A rí baba lónìí a rí baba”
Jònto, a rí baba
“Á rí baba lónìí a rí baba”
Jònto, a rí baba
Sàsóré lóun dáràn
“Owó àwon wo lòún tún bó sí yìí”?
Gbígbé ti wón gbé e dé ìlú
Orí àga Oba ni ón gbé e kà
Ni ón bá fi Sàsóré dédù oyè
Sùgbón oyè Oba Ìbínní tóbi ju ti Eléwìí lo
Gbogbo Oba kéékèèké bí Eléwìí
Ní n be lábé Oba Ìbínní
Ngbè ó yá gbogbo àwon Oba kéékèèké lòó kí Oba tuntún
Eléwìí náà mú aso
Yóó lòó kí eni ti ón fi joba
Tóun jù sínú odò
Ngbàa wón dé òhún
Ó rí Sàsóré
Ló jókòó nbi wón gbé adé lé e lórí
Gbogbo wón n yíràá
Kára ó le. Kára ó le
Sàsóré n pé e lòó jókòó
Eléwìí bá n gbòn
“Eni tóun ní kí wón ó dé mó pósí”
“Kí wón ó jù sínú omi
“Lòún bá lórí oyè yìí”!
Ó dáké tòun tojora”
Ngbà ó dijó kejì
Ti ón je ti ón mu tán
Sàsóré bá pe Eléwìí
“Njé o dá òun mo”
Ó ní “Káábíèsí, n ò mò yín”
Sàsóré ní “o ò dá mo mò”?
“Bó pé o ò mò mí”
“Oró kó lo dá mi”
“Bóò bá hùwà tóo hù sí mi”
“N ò níí dé ipò ti mo wá yí”
“Bóo sì pó o mò mí”
“N ò síí se ó ní nnkan”
Ni Sàsóré bá n jó ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo náà n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Orí wo ibi rere gbé mi dé
Èsè wo ibi rere sìn mí rè
Ibi Oríi mi n gbé mií rè
N ò mo be
A díá fún Sàsóré
Èyí ti n lo rèé borí Eléwìí
Èyí ti Eléwìí dá lóró
Tó kàn mó pósí
Tó jù sínú odò
E è ri bí o?
Sàsóré wá là làà là
Ó wá ju Eléwìí náà lo
E è wa ráyé bí o
Sàsóré mòmò là.
Véase Iwori-Irete.