Versos de Onígòósùn en Iwori-Iroso
Revisión del 14:38 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos de Onígòósùn en Iwori-Iroso
Ìwòrì Gósùn
Gósùn gósùn abowó odó porogodo
A díá fún Onígòósùn omo Àpón
Ekún omo ní n sun
Òún le bímo báyìí?
Wón ní ó rúbo
Wón ní kókó Osùn mérìndínlógún lebo è
Òpòlopò owó lebo è
Ìgbà ti yóó bá sì rúbo
Wón ní kí wón ó mó fi ebo kàn án lórí
Igbáàyàa rè ni kí wón ó móo febo kàn
Wón lóríi rè ti n gbébo
Ayàa rè ni ò gbètùtù
Bí wón bá ti fi ebo kàn án láyà
Ti ón sì gbébo fún Èsù
Wón ní tiè ti dáa
Wón bá rúbo
Ìwòrì Gósùn
Gósùn gósùn abowó odó porogodo
A díá fún Onígòósùn omo Àpón
Ekún omo ní n sun
Oríi rè ti n gbébo n rírú o
Ayàa rè ni ò nígbà yìí ò
Ó sì bímo lópòlopò werere.
Véase Iwori-Iroso.