Versos de Ìwòrì ò bèrè en Iwori-Obara

De IFA Wiki
Revisión del 15:38 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Ìwòrì ò bèrè en Iwori-Obara

Àwon ajàkàsù n sunkún àwon ò yó
Kín leni ti n wa tinú orií je ó se
A díá fún Ìwòrì ò bèrè
Èyí tó lóun ò dúó de Ifá mó
Ó lóun n renú ìgbé rèé so
Gbogbo ire tíí móoó se déédé Ìwòrì ò bèrè
Gbogbo è ní n fò ó ru
Òún á a ti se sí?
Wón ní kó rúbo
Ó se é
Sùgbón kò ní sùúrù tó
Ó bá lóun ó lòó pokùn so
Oba àwon ará ìlú kejì sì kú
Ifá pé eni tó bá fé so ni kí wón ó fi joba
Nígbà ti Ìwòrì ò bere dé ibi ó ti féé so
Kó fi okùn borùn
Làwon ará ìlú òdíkejì bá mú u
Ni wón n se
Ìwòrì ò bèrè mòmò so
Ma mòmò bínú Orí oyè n bò
Ìwòrì ò bere mòmò so.

Véase Iwori-Obara.