Versos de Ìwòrì Ogbè en Iwori-Ogbe

De IFA Wiki
Revisión del 16:41 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Ìwòrì Ogbè en Iwori-Ogbe

Ìwòrìbogbè eye oko
A díá fún Òrúnmìlà
Bàbá jí
Baba ò rówó kan à á yóó ná
Òún leè lájé lówó báyìí?
Wón ní ó rúbo
Wón níre ajé fún Baba
Wón lójú ò níí pón on
Lésò lésò nire ó móo bá a
Òrúnmìlà rúbo
Ó rú òpòlopò okàa Bàbá
Àti owó
Wón da gbogbo è sójú opón
Ayé ye é
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìwòrìbogbè eye oko
A díá fún Òrúnmìlà
Bàbá jí
Baba ò rówó kan à á yóó ná
Wón ní ebo ni kí Bàbá ó se
Òrúnmìlà gbébo nbè ó rúbo
Ajé gbá rere wá
Kóo wáá bá mi
Àdàbà sùsùùsù gbá rere wá
Kó wáà jekà
Aya gbé rere wá
Kó wáá bá mi
Àdàbà sùsùùsù gbá rere wá
Kó wáà jekà
Omo gbé rere wá
Kó wáá bá mi
Àdàbà sùsùùsù gbá rere wá
Kó wáà jekà
Ire gbogbo gbá rere wá
Kó wáá bá mi
Àdàbà sùsùùsù gbá rere wá
Kó wáà jekà.

Véase Iwori-Ogbe.