Versos de Ìwòrì Òtúrúpòn en Iwori-Otrupon
Revisión del 18:01 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos de Ìwòrì Òtúrúpòn en Iwori-Otrupon
Ìwòrì tútù ninini
Bí ení sàádá
A díá fún Olomo ní ràdiràdi
Ekún omo ní n sun
Òún le bímo báyìí?
Wón ní kó rúbo
Ó se é
Nígbà ti iré ó kalè fún un
Lódidi lódidi nire rè n dé
Olomo ní ràdiràdi n losèé jé
Bée bá la omo Òsé
Gbogbo omo inú è nìkó òwú so pò
Tó sì kún délè
Òun náà?
Lòún níre lódilódi lódidi báyìí?
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìwòrì tútù ninini
Bí ení sàádá
A díá fún Olomo ní ràdiràdi
Ekún omo ní n sun
Wón ní ó sa káalè ebo ní ó se
Ó gbébo nbè
Ó rúbo
Rírú ebo
Èèrù àtùkèsù
E wáá bá w aní màrínrín ire
Màrínrín ire làá bá ni lésè oba Òrìsà
Olomo ní ràdiràdi n losè é jé.
Véase Iwori-Otrupon.