Versos de Ìwòrì Òtúrá en Iwori-Otura

De IFA Wiki
Revisión del 18:31 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Ìwòrì Òtúrá en Iwori-Otura

Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Kèké omo Olómìjó
Wón ní ó rúbo
Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Òkòtó omo Olómìjó
Wón ní ó rúbo
Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Àré tíí somo ìkéyìin won lénje lénje
Ebo n wón ní ó se
Wón ní kí àwon métèètá ó rúbo
Olómìjó tíí se baba won
Olóyè ni
Olómìjó wáá dàgbà
Ó re ibi àgbàá rè
Ení ó bá sì lè jó gorí awo
Ní wón e lédù oyè
Nì ó gorí ìtée babaa won
Kèké ní tóun ti mò ó jó
Táyé ye òun tó báyìí?
Ta aní ó gba ipòo babaa òun lówó òun?
Òkòtó ní tòun bá bèrè síí jó
Gbogbo èèyàn ní ó mò póun mò ó jó
Àré nìkàn ló lórí òun ò gbó
Ó rú odidi awo ti ón fíí solá
Ó rú bílálà ti ón fíí solá
Ìgbà ó tó àsìkò ti wón ó móo jó
Òkòtò jó jóó jó
Ò yípo bììrì
Kò le jó gorí awo
Kèké jó jóó jó
Ó fesè walè
Kò le jó gorí awo
Wón bá ní kí Àré ó bó síbè
Àré bá jó jóó jó
Kò le gorí awo
Èsù ní e gbòn ón ní bílálà
Wón gbé bílálà lé Àré léèkínní
Pèrè ló fòóké sùgbón kò gorí awo
Èsù tún gbòn ón ní bílálà léèkejì
Ó tún gbòn ón léèketà
Àfi tepón
Àré bá bóórí awo
Ngbà ó rúbo
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Kèké omo Olómìjó
Wón ní ó rúbo
Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Òkòtó omo Olómìjó
Wón ní ó rúbo
Ìwòrì wòtu pèèrèpè
A díá fún Àré tíí somo ìkéyìin lénje lénje
Bó bá dà kó rè Ìgo
Ìgbònngbòn
A gbé Ìgo dìde
Ìgbònngbòn
Àré nikàn rú n be léyìn tó rúbo
Ìgbònngbòn
Máa gbé Ìgo dìde
Ìgbònngbòn.

Véase Iwori-Otura.