Versos de Òbàrà Ìká en Obara-Ika

De IFA Wiki
Revisión del 18:48 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òbàrà Ìká en Obara-Ika

Gbogbo ohun táa bá n se
Ká má fàsejù kun
A díá fún Ode adèbìtì là
Èyí tí ó fodún méta dègbé Agílíntí
Ó dègbè dègbé dègbé
Òun le là báyìí?
Wón ní kó rúbo
Wón ní yóó là
Wón ní nítòsíi rè náà lolà wá
Ngbà ó dí odún keta
Níbi tí gbé n de èbìtì
Ó bá kan Agílíntí nlè
Agílíntí ní ìwo Ode dákun mó pa òun
Kín lò n wáá kiri?
Odé ní òún n dègbé kiri kóun ó leè là ni
Agílíntí ló dáa
Bò sòkòtò e sílè
Odé bá bó sòkòtò è
Ó ní kó bó èwu è
Ó bó èwù
Ó ní kó sí fìlà è
Ó sí fìlà
Ode bá wà níhòhò goloto
Agílíntí ní lòó fa òtàkùn tééré un
Odé bá fa pàntí ìtàkùn
Bó ti fa pàntí òhún
Ló bá bára è nílùú obìnrin
Ìlú obìnrin tó sì lòó bá ara è yìí
Ìhòòhò ni gbogbo àwón wà nbè
Àwon ò sì lÓkùnrin
Ni ón pò lo jàrá
Wón bá fowó gbé e lárá jó
Odé ní ‘luulu lúùlù ni’
Àwon Obìrin ní kó fi lu àwon wò
Gbogbo eni ó bá ti fi lù léèkan
Oyún ni ón n ní
Bí ón tí n bímo okùnrin
Ni ón n bí omo obìnrin
Bó bá sì jí lójúmó
Iye tó wù ú ní ó se
Ngbà tí ón ríi pé òun nìkan làwón gbékè lé
Wón bá fún Ode nílé
Wón fún un ní yàrá méta
Wón ní ‘iyàrá àkókó àti èèkejì’
‘Móo wò ó bó se wù ó’
‘Sùgbón èèketa un’
‘Mó wo inú è o’
Enu ibodè sì ni ilé è wà
Ilé rí rigindin bíí ààfin oba
Àwon Obìnrin bá kó ilé fún Ode tán
Odé n jayé
Wón ó wà lórí ìkúnlè
Wón ó mó o gbé oúnje fún un
Ngbà ó di ijó kan
Ode bá ní ‘ká ti gbó’
‘Pé Obìnrin ní ó móo pàse fún èèyàn’
‘Pé kóun ó mó wo ibìkan’
‘Ibìkan ni kóun ó móo wò’
Nnkan táa bá n se
Ká má fàsejù kun
A díá fún Ode adèbìtì là
Èyí tí ó fodún méta dègbè Agílíntí
Ode adèbìtì là
Wón fún o léèwò
Èèwò mó mò yin
Wón fún o léèwò
Bóo bá e yín èèwò
Ó se e gbé
Wón fún o léèwò
Èèwò mó mò yin
Odé bá wo iyàrá ìketa
Bó ti wo inú è gìjà
Ló bá bá ara è níbi ó bó aso è sí lójó kìíní.

Véase Obara-Ika.