Versos de Òbàrà Ìrosùn en Obara-Iroso
Revisión del 19:17 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos de Òbàrà Ìrosùn en Obara-Iroso
Òbàrà kosùn sápá
Òbàrà kosùn sésè
Òbàrà kósùn sápá kosùn sésè kóo dá ribiribi ojú sí
A díá fún Eyelé
Èyí tí n fomi ojúú sògbérè omo
Wón ní kó rúbo
Ayé ye òun báyìí?
Eyelé bá rúbo
Ní bá n bímo méjì méjì
Òkan Ako
Òkan Abo
Ayé ye Eyelé
Ní wá n jó n ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òbàrà kosùn sápá
Òbàrà kosùn sésè
Òbàrà kósùn sápá kosùn sésè kóo dá ribiribi ojú sí
A díá fún Eyelé
Èyí tí n fomi ojúú sògbérè omo
Wón ní ó sá káalè
Ebo ní ó se
Eyelé gbébo nbè
Ó rúbo
Èyin ò mò pé méjì lEyelé n bí?
Eyelé won è é bíkan.
Véase Obara-Iroso.