Versos de Òróòtólú y Aréfunwè en Obara-Ofun

De IFA Wiki
Revisión del 21:13 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òróòtólú y Aréfunwè en Obara-Ofun

Òróòtólú
A díá dún Lámoko tíí báwoòn gbélé Alárá
Agò Lagòo Mèsìlà
A díá fún Erigí dúdú Igbódù Arèhan
Igbó nlá làá wo ká tóó wolé Olúsefun
A díá fún Pemópemó òde Àkúré
Nnkan àwon dáa ni ón bèèrè sí
Òróòtólú, díá fún Lámoko tíí báwoón gbélé Alárá
Nnkan ò se òun; nnkan ò se omo òun?
Agò Lagòo Mèsìlà, díá fún Erigí dúú Igbódù Arèhan
Obìnrin òun ò kú òun náà ò kú?
Igbó nlá làá wò ká tó wolé Olúsefun
A díá fún Pemópemó òde Àkúré
Òun sòwò òún lówó
Loóko à á pé Ògún
Wón ní kí wón ó rúbo
Òróòtólú
A díá fún Lámoko tíí báwoón gbélé Alárá
Wón ní àgbébò adìe lebo è
Agò Lagòo Mèsìlà
A díá fún Erigí Igbódù Arèhan
Wón ní Àkùko adìe lebo
Igbó nlá làá wò
Ká tó wolé Olúsefun
A díá fún Pemópemó òde Àkúré
Wón ní òpòlopò eku lebo è
Òpó Ìmòdò níí rìn
Lábàtà níí yín koroyín kòròyín
Òun náà lo díá fún Aréfunwè aya Àgbonnìrègún
Obìnrin kan le bímo báyìí?
Ló dá Ifá sí
Wón ní Ewúré lebo
Wón ló já ònà
Wón bá rúbo
Nnkaan wón dáa
Nnkaan won ò bàjé mó
Ni wón wá n jó n ní wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Wón ní béè làwon Babaláwo tàwón wí
Òróòtólú
A díá dún Lámoko tíí báwoòn gbélé Alárá
Agò Lagòo Mèsìlà
A díá fún Erigí dúdú Igbódù Arèhan
Igbó nlá làá wo ká tóó wolé Olúsefun
A díá fún Pemópemó òde Àkúré
Òpó Ìmòdò níí rìn koroyín kòròyín
A díá fún Aréfunwè aya Àgbonnìrègún
Aréfunwè o kan omo
Òpó Ìmòdò ló mú o wá MÈdú
Aréfunwè o kan omo.

Véase Obara-Ofun.