Versos de Kànsièrè en Obara-Osa
Revisión del 22:13 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos de Kànsièrè en Obara-Osa
Òbàrà ò sá kùúkùú
Òbàrà ò sá kèékèé
A díá fún Kànsièrè
Èyí tí ó fi gbogbo ara è bímo
Òun le bímo báyìí?
Ni Kànsièrè bá mú eé kún eéta
Ló bá roko aláwo
Wón ní kó rúbo
Kànsièrè làá pe àgbébo adìe
Kànsièrè bá rúbo
Ó rúbo tán ló ba bèrè síí bímo
Ní ó kómo léyìn yo yoo yo
Láyé ye é
N ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo è n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òbàrà ò sá kùúkùú
Òbàrà ò sá kèékèé
A díá fún Kànsièrè
Èyí tí ó fi gbogbo ara è bímo
Tá ló bímo báwònyí beere?
Kànsièrè
Ló bímo báwònyí beere
Kànsièrè.
Véase Obara-Osa.