Versos de Òpéèré y Onídòko en Obara-Oshe

De IFA Wiki
Revisión del 22:29 28 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òpéèré y Onídòko en Obara-Oshe

Òpéèré Awo ilé Onídòko
Ló díá fún Onídòko ní kùtùkùtù Àwúrò
Níjó tí Olóbàrà n lo rèé fé omo Onídòko pàá
Wón ní kó rúbo
Wón ní omo won kan n be tó ti tóó lókó
Wón ní Awo ló lomo òhún
Won ò rúbo
Òbàràòsé bà sawo dé ilé Onídòko
Ó bá lóun fé féé omo Onídòko
Ngbà ó tó gégé ìgbà tí omo ó móo lo ilé oko è
Won ò bá gbo ohun tí Bàba Onídòko n so mó
Won ò gbó ohun tí Ìyá Onídòko n wí mó
Òpéèré sì ti dá Ifá fún Onídòko télè
Ní bá n pé
Omo Onídòko ò
Omo Onídòko ò
Omo Onídòko ò níláárí
N ni Òpéèré n wí tée dòni
Wón ní nígbà tí Onídòko ò fomo è fún Awo mó ni
Òpéèré Awo ilé Onídòko
Ló díá fún Onídòko ní kùtùkùtù Àwúrò
Níjó tí Olóbàrà n lo rèé fé omo Onídòko
Omo Onídòko ò wáá fé e mó
Òpéèré nlé o Awo ilé Onídòko
Ó n bú Ìyá Onídòko
Ó ní Ìyá Onídòko ò níí sí
Òpéèré nlé o Awo ilé Onídòko
Ó n bú Bàbá Onídòko
Ó ní Bàbá Onídòko ò níí sí
Òpéèré nlé o Awo ilé Onídòko
A ko omo Onídòko
A ò fe mó.

Véase Obara-Oshe.