Versos Àsèsè ràn Oòrùn en Ofun-Iroso

De IFA Wiki
Revisión del 08:04 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Àsèsè ràn Oòrùn en Ofun-Iroso

Àsèsè ràn Oòrùn
Níí faraá jàjà lára ògiri
A díá fún Òfún
Èyí tí n lo rèé gbé Olósùn níyàwó
Wón ní kó rúbo
Nígbà tí Òfún ó fèé aya
Olósùn ló fé
Wón ní kí wón ó rúbo omo
Wón bá rúbo
Olósùn ò wáá mò pé aso Osùn lóùn ó wàá
Tí òun í fi móo bo àwon omo òun
Bílè bá ti sú
Àwon omo ò bá jé kí won ó sùn
Wón bá to Òrúnmìlà lo
Gba àwon dákuùn!
Òrúnmìlà ní kí wón ó tójú aso Osùn
Kí wón ó móo fi àwon omo lára
Òrúnmìlà ní gbogbo iree yín pò
Ifá pé bí aso yìí ò bá wón won
Gbogbo ará Ilé eléyìun ò níí fé rere kù
Ni ón bá se béè
Ni ón n fi aso Osùn bo àwon omo lára
Ni ón bá n sùn
Iré bá n wo ilée won
N ni wón wá n jó ni wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tàwón wí
Àsèsè ràn Oòrùn
Níí faraá jàjà lára ògiri
A díá fún Òfún
Èyí tí n lo rèé gbé Olósùn níyàwó
Ebo n wón ní ó se
Ó wáá gbébo nbè
Ó rúbo
Àsé Òfún Olósùn ló gbóge
Laà fi tètè sùn?
Laà fi tètè wo?
Àsé Òfún Olósùn ló gbóge
A wáá gbébo nígbà yí ò
A rúbo
Òfún Olósùn won ò gbòge mó.

Véase Ofun-Iroso.