Versos Igi Gbígbe ni ò léwé en Ofun-Ogbe

De IFA Wiki
Revisión del 16:59 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Igi Gbígbe ni ò léwé en Ofun-Ogbe

Igi gbígbe ni ò léwé
Àfòmó ni ò légbò
A díá fún Míèéyè
A bù fún Ayaa re
Nijó tí wón n sunkún àwon ò lajé lówó
Àtoko àtìyàwó ni ón pàwon ò lajé lówó
Súgbón kíké tí okó n ké
Ó pò ju ti Obìnrin è lo
Okó wáá ni àwon adìe kan tí n sìn
Òkan nnú àwon adìe òhún bá kú
Okó bá bú púrú sékún
‘Adìe tí òún gbékè lé pàwon ó tà’
Tàwon ó móo fowó è jeun
Adìe òhún náà ló kú yìí!
Ó bá bèrè síí ronú
Èsù bá dé
Ó ní ‘yan adìe náà pamó’
Míèéyè bá yan adìe pamó
Ojó yí lu Ojó
Osù yí lu Osù
Kùkùsajà wáá mú omobìnrin Olókun
Omo Olókun ò gbádùn
Olókun ba lòó bá àwon Awo è
Wón ní bó bá rí òkú adìe
Omoo rè ó gbàádùn
Òkú adìe ni wón e sètùtù fun
Wón bá n wá òkú adìe kíri
Èsù tí n sèhín sòhún
Òún bá gbó
Ó bá so fún on pé òkú adìe n be nlée Míèéyè
‘Míèéyè ni e móo wá lo’
Nígbàa wón e dé ilée Míèéyè
Èsú ti débè
Ó ní so fún won pé igba òké lóó ta adìe
Igba òké njó ojó náà
Erù owó ni
Lóòtó àwon ti n wa òké adìe dé
Wón figba òké lélè
Wón gba adìe
Wón bá lòó fi sètùtù fómo Olókun
Omo Olókun bá gbádùn
Nígbà ó tún se sàà
Kùkùsajá tùn mú omo Olósà
Òun náà rù ú
Ó sò ó
Wón ní kóun náà ó móo wá òkú adìe lo
Wón tún júwe ilée Míèéyè
Adìe rè kan ti tún kú
Ó tún yan án pamó pé bóyá Olóun a jé ó tún rí béè
Wón tún san irú owó tí Olókun san
Igba òké tún bó sówóo Míèéyè
Ó tún dà á sápò
Sùgbón léèkínní àti léèkejì
Ìyàwóo Míèéyè ni wón bá nlé
Òun ní ó lòó pe oko è wá
Pé ón féé ra òkú adìe
Míèéyè bá pa gbogbo owó tán
Kò fún Obìnrin ní nnkan nnú è
Obìnrin bá ko bà
“Oko òun ò tiè bun òun ní nnkan nnú owó yìí”!
Obìnrin Míèéyè náà bá mú òkan nnú àwon adìe tiè
Ó bá lù ú nó gbóngó
Adìe bá kú
Ó bá yan án
Ó fi pamó
Ó tún pé sàà
Kùkùsajà tún dé sí omo Olókun mìíìn
Olókun ní àwón ti mo ibi tàwón tíí ra òkú adìe
Wón bá tún korí sílée Míèyè
Èsù ní sìí tèlé won
Ní gbogbo ìgbà tí wón bá n bò
Bí ón ti dé ibè
Obìnrin ni ón tún bá nlé
Obìnrin bá lòó mú adìe tiè tó lù ní gbóngbó pa fún won
Wón ó móo ka owó
Èsù ní e dúó
Njé adìe yìí kú fúnraa rè bí?
Torí ìmònràn lòun
Ó ti mo nnkan tó kú yàtò sí èyí tí ón lù pa
Èsù ní kí wón ó fì adìe sílè
Obìnrin bá bú sékún
Nígbà ó dìgbàa tòún
Ni wón ko adìe sílè
Ní n hu bí enii wón dá lóró
Wón ní ‘a kìí forí wé Orí’
‘Ìwo lo fOrí araà re wé ti Míèéyè okoò re’
Ifá pé kí Obìnrin eléyìí ó mó bìínú o
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Igi gbígbe ni ò léwé
Àfòmó ni ò légbò
A díá fún Míèéyè
A bù falla rè
Nijó tí wón n sunkún àwon ò lajé lówó
Ebo n wón ní wón ó se
Míèéyè nìkán ló gbébo nbè
Ló fòótó rúbo
Èèwò Òrìsà
A kìí forí woríi Míèéyè layé.

Véase Ofun-Ogbe.