Versos Ewúré ilé yìí en Ofun-Ogunda
Revisión del 17:22 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos Ewúré ilé yìí en Ofun-Ogunda
Ewúré ilé yìí
Kèè tíì dé
Àgùtàn ilé yìí
Kèè tíì dé
Àwon ìkà ènìyán pète pèrò
Wón láwon ó gbóbì fún Babaláwo pé kó le róhun mú je
Wón ní kó rúbo
Babaláwo bá rúbo
Bí ón bá pé àwón ó fùún Babaláwo lóbì je
Araa won ni wón n báá jà
Won ò leè fún Babaláwo lóbì jè mó
Gbogbo èrò burúkú ti wón n rò lé e lórí
Asán ló já sí
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ewúré ilé yìí
Kèè tíì dé
Àgùtàn ilé yìí
Kèè tíì dé
Àwon ìkà ènìyán pète pèrò
Wón láwon ó gbóbì fún Babaláwo pé kó le róhun mú je
Wón ní kí Babaláwo ó rúbo
Awó gbébo nbè
Ó rúbo
Owó tewée ‘Má mu lò mí’
Owó tewée Róro
Àlòrìn lekòlóó fenuú lolè.
Véase Ofun-Ogunda.