Versos Mo sányán sányán en Ofun-Ojuani
Revisión del 17:38 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
Versos Mo sányán sányán en Ofun-Ojuani
Mo sányán sányán
Mo féèé kú
A díá fún Òrúnmìlà
Tí Babá ó dolóbè lóla
Wón ní ko rúbo
Wón ní kó gún Iyán
Kée bo òkè ìpòrí è
Kó wáá bu òkèlè méje nnú Iyán òhún láì lóbè
Kó lòó fi lé ibi òkè ìpòrí è
Kó pé bóun tíí je é nùu láì lóbè
Dandan ni kíre òún ó dé
Wón ní àyípadà ó ba
Òrúnmìlà se béè
Gbogbo nnkan bá yí padà sí rere
Ní bá n jó ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Mo sányán sányán
Mo féèé kú
A díá fún Òrúnmìlà
Tí Babá ó dolóbè lóla
Ebo n wón ní kí Babá ó se
Òrúnmìlà gbébo nbè
Ó rúbo
Ó tí n sányán sányán bíi féèé kú o
Ìgbèyìn
Babá wáá dolóbè o
Ìgbèyìn.
Véase Ofun-Ojuani.