Versos Òfún sà á léfun en Ofun-Osa

De IFA Wiki
Revisión del 18:27 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Òfún sà á léfun en Ofun-Osa

Òfún sà á léfun
Òfún sà á lÓsùn
Òfún sà á ní mòrìwò òpè ye yèè ye
A díá fún Alágemo tééré
Èyí tíí se wolé wòde Òrìsà
Wolé wòde Òrìsà ni Alágemo
Nígbà ó dijó kan
Alágemo bá rò ó
Ó bá sá kúò lódò Òòsà
‘Òòsà eni òdòò ré nko’?
Ó lóun ò ri mó
Òun ò sì tíì fún láse
Nbi Alágemó lo
Ó se see se
Kò ba mu
Wón lóó tùún padà lo òdò Òòsà tóo ti kúò
Ó bá padà sódò Òòsà
Òòsà níwo Alágemo
O ò níí kú
O ò níí rùn
Èmíì ré ó gùn
Sùgbón móo rora se
Alágemo bá rora n telè gélé
Ayé ye é
O ni Òfún sà á léfun
Òfún sà á lÓsùn
Òfún sà á ní mòrìwò òpè ye yèè ye
A díá fún Alágemo tééré
Èyí tíí se wolé wòde Òrìsà
Rírú ebo
Èèrù àtùkèsù
Ayé wáá ye wá tùtúru.

Véase Ofun-Osa.