Versos Bójú ò bá ròhún en Ofun-Otura

De IFA Wiki
Revisión del 20:20 29 nov 2026 de Maintenance script (discusión | contribuciones) (Ampliación del odu y sus referencias internas; revisión de textos y enlaces.)
(dif) ← Revisión anterior | Revisión actual (dif) | Revisión siguiente → (dif)
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Bójú ò bá ròhún en Ofun-Otura

Bójú ò bá ròhún bí okùn bí okùn
Kó leè róhun bíide bíide
A díá fún Ontòólá
Omo Atàgùtàn solà
Akúsèé pátápátá ni Ontòólá
N sì n dá oko
Ó ní Àgùtàn kan
Ti bá n looko láàárò
Yóó mùú Àgùtàn è lówó
Yóó mu lo inú oko
Bí bá sì n bò lósàán
Tòun tàgùtan è ní ó móo bò
Lójó kan tí Ontòólá wà lóko
Ontòólá n roko pèlú Àgùtàn léyìin rè
Àgùtàn bá fòhún èèyàn
‘Ontòólá, ìyá yìí mò pò o’!
Ontòólá ní bóo ló ti jé
Àgùtàn òun ló sòrò yìí
Obá ó sì gbó
Ó bá forí lé Ilé oba
Káábíèsí oba
Òún rí nnkankan tóun ò rí rí o
Wón ní kín ní?
Ó lágùtàn òún n be nbi tóun so ó mó lóko
Ó sì sòrò lónìí
Háà!?
Àgùtààn ré sòrò?
Iró leléyìí n pa yìí o
Ó níró kó
Òun ò paró
Àgùtàn òún sòrò lóòótó ni
Wón bá ní wón ó lòó mú Àgùtàn òhún wá
Pé ó wá tún òrò òhún so fáàfin lójúu gbogbo èèyàn
Wón mú Àgùtàn dé ibè
Njé ìwo Àgùtàn
O ò wa sòrò kóo wíhun tóo wí fóba
Ló bá di wò mí n wò ó
Àgùtàn ò sòrò mó
Bóo láa jé?
Ó gbo Àgùtàn jìgìjìgì
Àgùtàn ò dún
Obá ní kí wón ó mú u
Kí wón ó dè é
Ìwo wáá puró fóun
Òun odidi oba aládé
Wón ní kí wón ó lòó pe àwon béríbérí wá
“Wón mò féé pa òun ìwo Àgùtàn yìí”!
“O ò wa sòrò dákun”
Àgùtàn dúó ntiè
N wo olówóo rè gbùun
Àwon béríbérí bá dé
Wón fa idà yò nnú àkò
Njé kí wón ó gbé idà sókè
Kí wón ó bé oríi Ontòólá
Àgùtàn bá lanu è
Ó ní ‘E mó pa á o’
‘Èèmò’
Owó ení ó féé bé Orí Ontòólá gan
Kò le gbé idà wálè mó
Àgùtàn tún wí léèkejì
‘E mó pa á o’
Ó ní ìwo Ontòólá
‘O ò mò pé bójú ò bá róhun bí okùn bí okùn’
‘Kò leè róhun bíide bíide’
‘E mó pa á o’
Wón bá tú Ontòólá sílè
Wón bá fi òpòlopò orò jìn ín
Ijó ní n jó
Ayò ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Bójú ò bá róhun bí okùn bí okùn
Kò leè róhun bíide bíide
A díá fún Ontòólá omo Atàgùtàn solà
Wón ni ó káàkí mólè ó jàre
Ebo ní ó se
Ó sì gbébo nbè
Ó rúbo
Njé rírú Ebo
Èèrù àtùkèsù
Kèè pé o
Ònà è jìn
E wáá bá ni ní jèbútúu re
Jèbútú rere làá bá ni lésè oba Òrìsà

Véase Ofun-Otura.