Versos Ìdin sùkú sùkú en Odi-Oyekun

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Ìdin sùkú sùkú en Odi-Oyekun

Ìdin sùkú sùkú
Awo Àgbon ló dífá fún Àgbon
Níjó tí Àgbon ń fojúú sògbérè omo
Wón ní ó rúbo
Wón ní gbogbo omo rè ó níí yàtò síra
Wón ní sùgbón adìe àgò lebo
Àgbon bá rú adìe àgò kan
Àgò òhún ní ón fi ń kó àgbon lórùn
Tée dòní
Bí Àgbon bá ti ga ju èèyàn lo
Tí ón sì fé kómo ó dúró lára è
Kùňkú ni wón e kó o lórùn
Àgbon tó lè kún kùňkù
Ní ń be nínúu siiri àgbon kan
Ayé ye é
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìdin sùkú sùkú
Awo Àgbon ló dífá fún Àgbon
Níjó tí Àgbon ń fojúú sògbérè omo
Wón ní ó sá káalè ó jàre ebo ní ó se
Àgbon gbébo ńbè
Ó rúbo
Taa ló bímo báwònyí kandi kandi?
Àgbon nikàn ló bímo báwònyí kandi kandi
Àgbon nikàn
Èyin ló pé omo Àgbon pò láyé.

Véase Odi-Oyekun.