Versos de Àjàgùnmòlè en Odi-Oshe

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Àjàgùnmòlè en Odi-Oshe

Ìdin sé o
Ìrèlè sé o
Igi ogbà sé
Kéni ó lòmíìn
Oko kú
Kí n lóko
Àlè kú
Kí n yàn òmíìn
Béní orí ení ò bá kú
Ení ilèélè ò le deni orí ení
A dífá fún Àjàgùnmòlè
Èyí tíí solóríi gbogbo Awo lálàde òrun
Wón ní ó rúbo
Wón ní tí bá tí ń bo òkè ìpòrí è
Wón ní ò si nňkankan tó kù mó
Ó se é
Ayé ye é
Èmí è gùn
N ní wá ń jó ní ń yò
N yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo ń yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìdin sé o
Ìrèlè sé o
Igi ogbà sé
Kéni ó lòmíìn
Oko kú
Kí n lóko
Àlè kú
Kí n yàn òmíìn
Béní orí ení ò bá kú
Ení ilèélè ò le deni orí ení
A dífá fún Àjàgùnmòlè
Èyí tíí solóríi gbogbo Awo lálàde òrun
Bí n bá rówó ní
Ó dorùn re
Ìwo Àjàgùnmòlè
Ó dorùn re
Bí ň bá ráya ní
Ó dorùn re
Ìwo Àjàgùnmòlè
Ó dorùn re
Bí ň bá rómo bí
Ó dorùn re
Ìwo Àjàgùnmòlè
Ó dorùn re
Bí ň bá rílé kó
Ó dorùn re
Ìwo Àjàgùnmòlè
Ó dorùn re
Bí mo bá e kú
Ó dorùn re
Ìwo Àjàgùnmòlè
Ó dorùn re.

Véase Odi-Oshe.