Versos de Òbàrà Òtòkú en Obara-Otrupon

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òbàrà Òtòkú en Obara-Otrupon

Ó kó nádúnádú bí eni oko ò bá seré
Ó kó kùkùkèkè kùkùkèkè bí eni oko ò bá sòrò
A díá fún Òbàrà Òtòkú
Omo a rà, à á rà soko
Wón ní kó rúbo
Òbàrà Òtòkú ni ò rí Okùnrin bá a seré
Wón ní yóó rìí Okùnrin bá seré
Wón ní kó móo terí ba fún okùnrin
Wón ni ‘ìwo lóó lòó tójú Okùnrin láyé’
‘Ó móo là móo lówó’
‘Sùgbón ó ó tiiri fún okùnrin’
‘Lóó fi gbádùn gbogbo nnkaàn re’
‘Ó ó ra oko ni’
‘Kóo mó baà sìnà’
Ó kó nádúnádú bí eni oko ò bá seré
Ó kó kùkùkèkè kùkùkèkè bí eni oko ò bá sòrò
A díá fún Òbàrà Òtòkú
Omo a rà, à á rà soko
À n rà egbèje
À n rà egbèfà
Àgbà tó lówó lówó
E wá rÈdú soko
Ení ó lówó lówó
Òbàrà Òtòkú bá ra Èdú
Ló bá fi Òrúnmìlà soko è
Èmí è bá gùn
Ló bá bèrè síí bímo
Ni ón bá là
Ifá pé kí eléyìun ó móo tójú okoo rè.

Véase Obara-Otrupon.