Versos Òòrun ló kan àtàrí en Ofun-Ika

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Òòrun ló kan àtàrí en Ofun-Ika

Òòrun ló kan àtàrí jìndùn jìndùn
A díá fún Bongágà obìnrin Ààtàn
Obìnrin Ààtàn ni Bongágà
Wón níwo Ààtàn rúbo fún obìnriìn re
Ti ò tíì dé ibì kankan tó gbé gèlè pénpé sórí
Bílè bá ti mó
Bongágà ó ti gbé adé lórí
Nígbà tí ó bàá e dòsán
Ó ti rè
Wón ní Ààtàn rúbo
Kí obìnriìn rè yìí ó lè ayé pé
Ààtàn ní kí Bongágà ó mú gèlè orí è wá
Bongágà ò dáhùn
Àyìn éyìn ni Bongágà n yin àwon Babaláwo è
Ó ní Òòrun ló kan àtàrí jìndùn jìndùn
A díá fún Bongágà obìnrin Ààtàn
Ìgbà àì sebo
Ìgbà àì tùèèrù
E è ri bí Bongágà tí n ba ikúú lo.

Véase Ofun-Ika.