Versos Òfún lawo ìgándó en Ofun-Iwori
Versos Òfún lawo ìgándó en Ofun-Iwori
Òfún lawo Ìgándó
Ìwòrì lawo Ìgándò
Òràn gándo gàndo ò tán nlè yí bòrò bòrò
A díá fún àgbààgbà méfà
Èyí tí gbogboo wón rojó enuu won
Tí gbogbo won ó sì móo jàre
Wón ní kí wón ó rúbo
Wón ní òmìmì kán n bò wáá mì wón
Oká leni àkókó
Nnú àwon àgbààgbà ló wà
Kèé sìí sún mó èèyàn
Gbogbo nnkan tó bá sún mó
Gbogboo wón ni wón ó ho fún un
Òkété lenìkejì
Òkéré nìketa
Èlulùú lenìkerin
Àparò òyèyè leni ìkarùún
Àáyá lenìkefà
Gbogboo won ni wón jo n gbé láì síyonu
Wón níwo Òkété rúbo
Kóo mó baà rí ogun àwolébá
Òkété ní kín ní n jé ebo àwolébá?
Nígbà ó di òsán ojó kan
Oká n wá nnkan tí ó je kíri
Ló bá di wòò nnú Ilé Òkété
Bí Òkété se fojú kan Oká
Kín ló dí òun mólé yìí?
Ló bá jáde fòtì
Òkéré bá rí Òkété lóde òsán
Èèwò!?
A kìí réwú lóde òsán
Ókéré bá sáré gorí igi Ìrókò
Ó lójú òhun ò níí níkàn ríbi
Sáá sáá sá fò n lòkéré n ké
Èlulùú gbó
Òun náà figbe èèmo benu
Èjé ru leye oko n ké
Èlulùú ní ‘ó seése kí òré òun ti rí nnkan ewú ló fi ní kóun ó fò’
Àparò òyèyè gbó lóko
Òun náà bá figbe bonu
Ìlú ra
Àáyá gbó tí Àparò n ké pé ìlú ra
Hího lÀparò ho
I balanga; I balanga
Àáyá kolu èyin Etù
Èyin Etù fó
Etù bá fò
Ó bóórí igi
Ní bá n ké
E pé è
Nnkán ti bàjé
Ìlú e pé è
Wón bá pe gbogbo ìlú jó
Kín le a rí o?
Ìwo Etù kín lo pe àwon fún?
Etu lóun ò mo ibi tí Àáyá ti wá
Gbogbo èyin òun ló ti fó tán
Wón ní kí wón ó lòó pé Àáyá wá
Àáyá kín ló dé tóo fi fó èyin Etu?
Àáyán ní nígbà tí òún n gbó pé ìlú ra
‘Ìlú ra’
Bógun ò bá sì dé
Enìkan a lè móo ké pé ìlú ra bí o?
Taa ló a pé ilú ra fún o?
Ó ní Àparò òyèyè ni
Wón ní wón ó pe Àparò wá
‘Èése o Àparò’?
Òun náà ní nígbà tòún náà gbó tí Èlulùú nké èjé ru
Èjé ru lòón gbó tóun fí n kígbe béè
Ìwo Èlulùú kín ló dé?
Èlulùú ní nígbà tóun gbó tí Òkéré n ké
Òkéré n ké pé kóun ó sá fò ‘sá sáá sá fò’
Sáá sáá sá fò
Òkéré kín lo rí o tóo fi pé kí Èlulùú ó fò?
Òun náà ní nígbà tòún rí Òkété lóde òsán
TÒkété è é sìí jáde òsán
Lòún sì ri tí Òkété n sáré àsápajúdé
N náà ló mú òun tóun fí n ké
Ìwo Òkété bóo ló se jé tée fi jáde lósàán gangan?
Òkété ní jééjé òun lòún jókòó
LOká bá wá káun mólé
BÓká bá sì ká èèyàn mólé
A wa móo rorùn bí?
Ìwo Oká kín lò n wá nnú ilé Òkété?
Oká ní òún n wá nnkan tí òún ó je kíri ni
Òun ò sá mole eníkan yàtò
Gbogbo àwon tí n be nbè ko hà!
Taa la wá rí dá lébi nnúu yín?
Ifá pé ká má se àsìgbó òrò
Ká móo wádìí òrò dáadáa ká tóó se òhúnkòhún
Etú ló pe gbogboo won jo
Ará bá tu gbogboo won
Ni won wá n jó ní wón á n yò
Won n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Wón ní béè làwon Babaláwo tàwón wí
Òfún lawo Ìgándó
Ìwòrì lawo Ìgándò
Òràn gándo gàndo ò tán nlè yí bòrò bòrò
A díá fún àgbààgbà méfà tí gbogboo wón rojó enuu won
Gbogboo wón rojó enuu won
Won ò níí lébi
Opélopé Etú ló jára ó tù wá
Àwá deni olà peregede.
Véase Ofun-Iwori.