Versos Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo en Ofun-Oyekun

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo en Ofun-Oyekun

Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo
Wón ló di fèèrè i tìmó
Òrúnmìlà ló dùn jojo
Emi náà ló dùn jojo
Ifá ló dùn bíi kínni?
Wón ló dùn bí àmú omo eran
Òrúnmìlà lámùú omo eran ò tí dùn tó áráárá
Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo
Mo ló di fèèrè i tìmó
Òrúnmìlà ló dùn jojo
Emi náà ló dùn jojo
Ifá ló dùn bíi kínni?
Mo ló dùn bí àmú omo eku
Ifá lámùú omo eku ò tí dùn tó áráárá
Ifá wí ó ló di mómó jojo
Mo ló di fèèrè i tìmó
Òrúnmìlà ló dùn jojo
Emi náà ló dùn jojo
Ifá ló dùn bíi kínni?
Wón ló dùn bí àmú omo eja
Ifá lámùú omo eja ò tí dùn tó áráárá
Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo
Wón ló di fèèrè i tìmo
Òrúnmìlà ló dùn jojo
Emi náà ló dùn jojo
Ifá ló dùn bíi kínni?
Wón ló dùn bí àmú omo eye
Òrúnmìlà lámùú omo eye ò tí dùn tó áráárá
Òrúnmìlà wí ó ló di mómó jojo
Mo ló di fèèrè i tìmó
Òrúnmìlà ló dùn jojo
Emi náà ló dùn jojo
Ifá ló dùn bíi kínni?
Mo ló dùn bí àmú omo eni
Ifá ni mo seun seun
Ifá pé àmú omo eni ló dùn
Ó lámùú omo eku ò tí dùn áráárá
Ó lámùú omo eja ò tí dùn áráárá
Àmú omo eye ò tí dùn áráárá
Àmú omo eranko ò tí dùn áráárá
Amú omo ènìyàn ò tí dùn
Àmú omo eni ló dùn ló jóyin lo
Omo ló ti dùn ló jóyin lo
Omo ló ti dùn
Omo ju àmú
Omo ló ti dùn ló jóyin lo.

Véase Ofun-Oyekun.