Versos Agogo ní n ró e pé péré en Ofun-Okana
Versos Agogo ní n ró e pé péré en Ofun-Okana
Agogo ní n ró e pé péré
Àràn gèjè ní n ró mò kómo jo mò kómo jo
A díá fún Kóórì
Èyí tí n fomi ojúu sògbérè omo
Òun le rómo bí báyìí?
Wón ní ó rúbo
Wón ní àgbédò adìe lebo
Ló bá pa adìe fúnra è
Nbè náà ló ti sè e
Nbè náà ló ti je é
Kò rómo kankan bí
Ó tún dèèkejì
Ó tún pa adìe
Ó tún dá a je
Kò rómo píìn
Nígbà ó dèèketa
Ó bá loòdò Òrúnmìlà
Hówù!
Wón ní kóun ó fi àgbébo adìe rúbo léèkíní
Òún fi rúbo léèkejì
Wón sì ní àwon omo n tèlé òun kíri
Òrúnmìlà níwo Kóórì loò seun
Ò n pa adìe
O sì n dá a je
Òrúnmìlà ní kí Kóórì ó lòó fi ìdodo kan ògiri
Lénu ibi ti ìdodo è bá ga mo lára ògiri
Kó sàmì síbè
Kó wáá pa adìe mìíìn
Kó mú eje adìe òhún
Kó fi yí ojú àmí ohun
Kí èjè adìe ó wáá sàn wálè
Kó sì ta epo díè sí ojú ibè náà
Òrúnmìlà ni kó mó je nbi adìe
Òrúnmìlà ní tí ò bá ti je nbè
Àwon omo ó tèle
Kóórì bá se béè
Ó bá kó gbogbo àwon èèyàn jo
Kò jè nnú è
Omó bá dé
Kóórì bímo yè
Ní bá n jó ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Agogo ní n ró e pé péré
Àràn gèjè ní n ró mò kómo jo mò kómo jo
A díá fún Kóórì
Èyí tí n fomi ojúu sògbérè omo
Tí sì n rodò tí ò rómo kó wálé
Ó lo nígbà èèkínní
Béè ni ò romo mú wálé
Ó lo nígbà èèkejì
Kò rómo mú wálé
Ni ón bá n korin fún Kóórì
Wón n pé bí ó lo
Kó móo lo
E jé Kóórì ó rodò
Bí ó lo kó móo lo
Ó japá
Ó jetan
Ó jèdí
Ó jèdò
Bí ó lo kó móo lo
Wón ní bí ti n padìe ní n dá je é
Ìgbà èèketa lÒrúnmìlà se Ifá fún Kóórì
Ó ní Kóórì o
Ó mò dé aréwe yò
Fún mi lómo kan n gbé jó.
Véase Ofun-Okana.