Versos Esè kan soso en Ofun-Otrupon
Versos Esè kan soso en Ofun-Otrupon
Esè kan soso ni mo tì bògbé
Igba eké ni mo sá
A díá fún Sàngó
Tí ó móo fòjò sìn kári ayé
Ebo n wón ní ó se
Bó bá ti dí Ìgbà òjò
Sàngó ó bèrè síí ro òjò sínú oko
Àwon Ònyagbè wá n wò ó pé kín làwón ó móo se báyìí láti dúpé?
Wón ní eni tí n ro òjò fún yin un ni e móo sìn
Òun náà ni Sàngó
Bi àwon Àgbè ba sì kò
Tí wón láwon ò se bíi ti Sàngó mó
Òdá ó bàá dá
Òòrun ó rán kankan
Bóo làwón o wàá se?
Wón ó bàá tún bo Sàngó
Bí ón bá ti bo Sàngó tán
Òjò ó rò ni
Gbogbo àwon èèyàn nígbà náà
Wón bá di olùsìin Sàngó
Bó bá ti àsìkò òjò
Nnkan wón n dára
Wón n tà wón n rà
Wón n jó wón n yò
Wón bá n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Wón ní béè làwon Babaláwo tàwon wí
Esè kan soso ni mo tì bògbé
Igba eké ni mo sá
A díá fún Sàngó
Tí ó móo fòjò sìn kári ayé
Ebo n wón ní ó se
Ó sì gbébo nbè
Ó bá rúbo
Rírú Ebo
Èèrù àtùkesù
Kèè pé o
Ònà è jìn
E wáá bá ni ní jèbútú ire
Njé a ó sìn sìì sìn
A ó fOrí sìn bí omo eku
A ó sìn sììn sìn
A ó fOrí sìn bí omo eja
A ó sìn sììn sìn
A ó fOrí sìn bí omo eran.
Véase Ofun-Otrupon.