Versos de Òbàrà Ìwòrì en Obara-Iwori

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òbàrà Ìwòrì en Obara-Iwori

Pékútúyeke Pékútúyeke
Ò tilè mí hìn hìn kanlè
A díá fún Ìwé
Èyí tí n lo rèé saya Àbàtà
‘Òun le bímo báyìí’?
Won ní kó rúbo
Wón ní òpòlopò omo ni Ìwé ó bìí
Ìwé rúbo
Ìwé sì bímo
Kàà kún
Funfun ni gbigbi àwon omo è
Wón ní ìwo Ìwé rúbo
Nígbà tóó wàá níwá, tóó léyìn tán
Rúbo àwon tí n ba nnkan je
Ìwé ní ‘Ní pèrèpèrè Àbàtà tóun wà yìí’?
‘Tóun sì bèrè síí bímo’
‘Kín ní ó mùú òun’?
Bí Ìwé bá sì bímo léèkan
Ó le bí irinwó
Ìwé bá bímo tan
Lààyé gbà á
Èsù bá so fún àwon Ònyagbè
Pé ilè tó dáa nbè lábàtà
Won bá palè oko
Wón bá tú ilé Ìwé sókè
‘Wón níwo Ìwé’
‘Àwon ò pé kóo rúbo Elénìní’?
Ni àwon Ònyagbè bá n hu Ìwé jáde
Ní wón wá n jó n ní wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Pékútúyeke Pékútúyeke
Ò tilè mí hìn hìn kanlè
A díá fún Ìwé
Èyí tí n lo rèé saya Àbàtà
Ebo n wón ní ó se
Enìkan ò mòmò bímo bí Ìwé mó o
Omo Ìwé pàpòjù!

Véase Obara-Iwori.