Versos de Òbàrà Òkànràn en Obara-Okana

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Òbàrà Òkànràn en Obara-Okana

Òbàrà Òkànràn
Bí Babaláwo bá gbófá
Bí ò bá gbófá
E jé á fÒbàrà Òkànràn lò ó wò
Òbàrà kànhìn kànhìn Awo ilé Òrúnmìlà
Lo díá fún Òrúnmìlà
Níjó tí n be láàrin Òtá
Wón ní kÍfá ó rúbo
Òrúnmìlà bá rúbo
Wón ní bíi idán ni ogún ó sèé
Òrúnmìlà bá rú Ewúré
Ó sì rú odán tí ón kùn léfun àti osùn
Wón fún Ewúré
Ewúré bá já a je
Ni ón bá fi rúbo fún Òrúnmìlà
Òrúnmìlà bá ségun bíi idán
N ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo è n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òbàrà Òkànràn
Bí Babaláwo bá gbófá
Bí ò bá gbófá
E jé á fÒbàrà Òkànràn lò ó wò
Òbàrà kànhìn kànhìn Awo ilé Òrúnmìlà
Lo díá fún Òrúnmìlà
Níjó tí n be láàrin Òtá
Ebo n wón ní ó se
Òrúnmìlà gbébo nbè
Ó rúbo
Rírú ebo
Èèrù àtùkèsù
E wáá bá ni ní àrúségun
Àwá ségun nígbà yí ò
Bí odán
Bí idán la ségun.

Véase Obara-Okana.