Versos de Ajílówó, Ajílórò y Màrìwò Òlé en Iroso-Otura

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Ajílówó, Ajílórò y Màrìwò Òlé en Iroso-Otura

Ajílówó Awoo won lóde Ìlówó
Ajílórò Awoo won lóde Ìlórò
Màriwò òlé níí sawo Ìlómò akuunu
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí ojú ti ń pón Ikin látèsín
Bàbá bá ké sí àwon Babaláwo è
Ó ní kí wón gba òun
Wón lebo ní kí Bàbá ó rú
Òrúnmìlà bá rúbo
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo ń yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ajílówó Awoo won lóde Ìlówó
Ajílórò Awoo won lóde Ìlórò
Mòriwò òlé níí sawo Ìlómò akuunu
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí ojú ti ń pón Ikin látèsín
Ebo n wón ní kí bàbá ó se
Ifá gbébo ńbè ó rúbo
Ojú ti ń pon ikin látèsín ńkó?
Òngò Isu
Kò sàì kóre ajé dé pòòrò
Òngò Isu
Ojú ti ń pon ikin látèsín ńkó?
Òngò Isu
Kò sàì kóre aya dé pòòrò
Òngò Isu
Ojú ti ń pon ikin látèsín ńkó?
Òngò Isu
Kò sàì kóre omo dé pòòrò
Òngò Isu
Ojú ti ń pon ikin látèsín ńkó?
Òngò Isu
Kò sàì kóre gbogbo dé pòròngòdò
Òňgò Isu.

Véase Iroso-Otura.