Versos de Gése en Obara-Otura

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos de Gése en Obara-Otura

Òbàrà Òtúrá ti oníkòó òwú
Babaláwo Gése ló díá fún Gése
Òkàdèmù lónàa tàdè
Níjó ti n sehun gbogbo tókan ò lójú
Nnkan òún le lójú báyìí?
Wón ní kó rúbo
Wón ní yóó rájé
Yóó laya
Yóó bímo
Gbogbo nnkan è ní ó dáa
Òwúùrù eyelé lebo è
Wón yan ebo fún Gése
Gése bá rúbo
Ayé bá ye Gése
N ní wá n jo n ní n yò
Ni n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òbàrà Òtúá ti oníkòó òwú
Babaláwo Gése ló díá fún Gése
Òkàdèmù lónàa tàdè
Níjó ti n sehun gbogbo tókan ò lójú
Wón lébo kíre ó le tó o lówó ni kó se
Gése wáá gbébo nbè ó wáá rúbo
Rírú ebo
Èèrù àtùkèsù
Gése wá n be ní wòwó ire gbàyí ò
N ó se tèmi
Àlúkèse oko ò sàì sere tiè lébè.

Véase Obara-Otura.