Versos de Iwòrì Òsé en Iwori-Oshe
Ir a la navegación
Ir a la búsqueda
Versos de Iwòrì Òsé en Iwori-Oshe
Ìwòrì wówó wówó
Ìwòrì wósù wósù
Ìwòrì wósù kóo tóó wàwo Òyìnbó
A díá fún Aláròóbò
A bù fún Baba Olóko
Wón ní wón ó rúbo
Baba Olóko n tajàa rè
Àwon Aláròóbò n rà
Baba Olóko ba n wo ìdí Aláròóbò
Kò wo ojà ti n tà mó
Ìwòrì wówó wówó
Ìwòrì wósù wósù
Ìwòrì wósù kóo tóó wàwo Òyìnbó
A díá fún Aláròóbò
A bù fún Baba Olóko
Tée ta gbogbo ojà nítàkutà tán
Ni ón bá n korin fún Baba Olóko
E è wowó lóóko ò
E e woowó lóóko ò
È n wòdí Aláròóbò o
E è wowó lóóko ò.
Véase Iwori-Oshe.