Versos de Sèkèrè en Obara-Oyekun
Versos de Sèkèrè en Obara-Oyekun
Òbàrà yékúé yèkùè yékúé
A díá fún Sèkèrè
Níjó tí n fomi ojúú sògbérè aya
Wón ní kó rúbo
Òun leè láya báyìí?
Wón ní ìwo Sèkèrè
Wón ní àwon ayaà ré ó pò
Ijó lóó móo jó
Lóo mo lù fún won o
Tóo bá tí n lù tóo sì n kàn fún won
Àwon Obìnrin ó gbàá tèlé o ni
Sèkèrè bá bèrè síí lù
Gbogbo Obìnrin kéékèèké bá gbá lé Sèkèrè
Ngbà tí ón jó jóó jó
Won ò mo ìgbà tí àwón bá Sèkèrè dé ilé
Wón bá dúó ti Sèkèrè
Ní ón bá n bímoó fún Sèkèrè
Ayé ye Sèkèrè
Owó pò tán ó bá tún so ó móra
Obìin è é sìí fowóó lè
Ni ón rówó
Ni ón dì mó o
Ni Sèkèrè wá n jo n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òbàrà yékúé yèkùè yékúé
A díá fún Sèkèrè
Níjó tí n fomi ojúú sògbérè aya
Won ní yóó láya lópòlopò ebo aya ni kó wáá se
A mòmò ti gbóru e rí
Àsé Sèkèrè ló fébìnrin èwe
A mò ti gbóru e rí.
Véase Obara-Oyekun.