Versos del viaje a Ènpe en Odi-Obara

De IFA Wiki
Ir a la navegación Ir a la búsqueda

Versos del viaje a Ènpe en Odi-Obara

Ìdin ń se mí gèlé gèlé
Olobàrà ní ń se mí gàlà gàlà
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí Bàbá ń sawoó ròde Ènpe
Òde Ènpe tóun ń lo yìí
Ó dáa fún òun ńbè bí?
Wón ní kí Òrúnmìlà ó rúbo
Wón ní yóó dáa fún un
Òrúnmìlà rúbo
Wón ní kó mó se iyè méjì o
Kó sì mó ja enìkankan níyàn
Wón ní bí ón bá ti pé bó ti rí nìí
Kó móo pé béè ni
Nígbà tí Òrúnmìlà dé òde Ènpe
Ayé ye é
Ajé dé
Ìdin ń se mí gèlé gèlé
Olobàrà ní ń se mí gàlà gàlà
A dífá fún Òrúnmìlà
Níjó tí Bàbá ń sawoó ròde Ènpe
Ebo n wón ní ó se
Wón ní kéni mó jiyàn lÉnpe
Ìdin ò jiyàn la fawo dá
Kéni mó jiyàn lÉnpe.

Véase Odi-Obara.